Alága(iwọ̀ orùn-àríwá),fún gbogbo ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress,Inuwa Abdulkabir ti papọ̀dà. Ó kú ní fẹ̀rẹ̀kùtù ọjọ́ ajé látàrí àìsàn rán pé tí ó ṣe é. Ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti ẹni tí ó tún jẹ́ akegbẹ́ rẹ̀ nínú ìgbìmọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní àsìkò ìgbà tí Adams Oshiomole jẹ́ alága ẹgbẹ́ òṣèlú […]

Arákùnrin Akeredolu yan Oluwatuyi gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé ìjọba Ìpínlẹ̀ Òndó titun Látàrí ìwé ìfi iṣẹ́ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé ìjọba Ìpínlẹ̀ Òndó tí Ifedayo Abegunde kọ,Gómìnà Rotimi Akeredolu ní ọjọ́ ajé ni ó ṣe ìkéde yíyan Temitayo Oluwatuyi gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé ìjọba Ìpínlẹ̀ titun ní Ìpínlẹ̀ náà. Gómìnà sọ di […]

Lẹ́yìn àìmọye ọjọ́ tí gómìnà Ìpínlẹ̀ Òndó ti lùgbàdì ààrùn korónà ni ó ti wà ní ìyàsọ́tọ̀, àyẹ̀wò ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé Gómìnà Ìpínlẹ̀ Òndó Arákùnrin Akeredolu, kò ní ààrùn kọ̀rónà mọ́. Gómìnà Akeredolu ni ó sọ́ eléyìí di mímọ̀ nínú ìròyìn ọjọ́ ajé.Ó sọ wípé àwọn dókítà […]

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Òndó, Arákùnrin Oluwarotimi Akeredolu, ti pàṣẹ wípé kí gbogbo ilé ìjọsìn jẹ́ ṣíṣí láti ọ̀la lọ. Àwọn ètò ìjọsìn, gẹ́gẹ́ bí Gómìnà ṣe sọ, gbọ́dọ̀ jẹ́ ṣíṣe pẹ̀lú mímú ìlànà tí ìjọba làkalẹ̀ lò. Arákùnrin Akeredolu wípé gbogbo ṣíṣe ètò ìjọsìn yí ó bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí àwọn […]

Ìjọba àpapọ̀ Orílèdè ti sọ wípé àwọn máa sọ àwọn ìlànà tí ó ní se pẹ̀lú ṣíṣí àwọn ilé ìwé tí wọ́n tìpa káàkiri orílèdè. Alága àwọn agbófinró tí óhún rí sí ààrùn kòrónà, Boss Mustapha, ni ó sọ di mímọ̀ ní ìgbàtí óhún sọ̀rọ̀ ní Abuja ní ọjọ́ ojọ́rú. […]