Gómìnà Ìpínlẹ̀ Òndó, Arákùnrin Akeredolu, ní ọjọ́ àìkú, ni ó hún yọ àwọn Gómìnà akegbẹ́ rẹ̀ púrò nínú ẹ̀sùn tí àwọn ará ìlú wón fi kàn wón wípé wọ́n gbé àwọn oúnjẹ tí ó yẹ kí wọn pín lásìkò àjàkálẹ̀ ààrùn kòrona pamọ ní ìpínlè wọn.
Púpọ̀ nínú ilé ìkẹ́rù sí tí ó wà ní àwọn Ìpínlẹ̀ ni àwọn ará ìlú ti lọ jí ǹkan kó lẹ́yìn ìwọde *EndSARS*.
Akeredolu, ẹni tí ó jẹ́ alága àjọ àwọn gómìnà ni gúúsù-iwoorùn, ni ó sọ pé ohun tí ó fa ìdádúro pínpín àwọn oúnjẹ náà ni pé àwọn Ìpínlẹ̀ kò tètè ríi gbà.
Gómìnà náà sọ̀rọ̀ yìí nígbà tí óhún sọ̀rọ̀ ní ibí ayẹyẹ ọdún kẹta oyè bísoopu ilé ìjọsìn Ọwọ, ilé ìjọsìn Nàìjíríà, Anglican Communion, Dókítà. Stephen Fagbemi, tí ó wáyé ní ilé ìjọsìn All Saints Church Idasen Owo, Ìpínlẹ̀ Ondo.
Ó wípé, “Àwọn Ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti gbé àwọn oúnjẹ wọ̀nyí pamó, náà dúró de àwọn oúnjẹ yòókù àti àṣẹ láti ọwọ́ ìgbìmò CA-COVID-19”.
Akeredolu tún ṣe àlàyé wípé ohun tí ó gba Ìpínlẹ̀ Òndó lọwọ jíjí àwọn oúnjẹ náà ni wípé wọn ti ń pín tiwọn.
Lórí ọ̀rọ̀ ìdìbò wọlé rẹ̀ padà, Akeredolu ṣe àpèjúwe ìṣẹ́gun rẹ ọjọ́ kẹwàá, oṣù Kẹ̀wá, níbi ètò ìdìbò Gómìnà gẹ́gẹ́ bí isẹ́ tí Ọlọ́run ti parí tí ènìyàn kò sì lè bàjẹ́, óse ìdánilójú wípé wí wọlé òhun ní èèkàn síi kò ṣe fọwọ́ kàn.