Ìjọba Ìpínlẹ̀ Òndó sí gbogbo ilé ìjọsìn padà

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Òndó, Arákùnrin Oluwarotimi Akeredolu, ti pàṣẹ wípé kí gbogbo ilé ìjọsìn jẹ́ ṣíṣí láti ọ̀la lọ.

Àwọn ètò ìjọsìn, gẹ́gẹ́ bí Gómìnà ṣe sọ, gbọ́dọ̀ jẹ́ ṣíṣe pẹ̀lú mímú ìlànà tí ìjọba làkalẹ̀ lò.

Arákùnrin Akeredolu wípé gbogbo ṣíṣe ètò ìjọsìn yí ó bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí àwọn tí jókòó pẹ̀lú gbogbo àwọn olórí ìṣe ìjọsìn.

Gómìnà ìpínlè Ondo tún sọ wípé tí wọ́n bá lè ṣe àmúlò ìdènà dáradára, àkọsílẹ̀ lórí irú ìjọ bẹẹ lè má tòhún kan.

Akeredolu ní wípé ọjọ́ etì nìkan ni wọ́n le kírun Jímọ̀, tí àwọn ẹlẹ́ṣin krìstẹ́níì yí ó máa lọ sí ilé ìjọsìn ní ọjọ́ Àìkú nìkan.

Ó ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn olórí ìjọ àti àwọn yòókù wípé kí wọ́n rí dájú wípé àwọn se àmúlò ìjìnà sí ara ẹni ní àwùjọ, kí wọ́n sì pèsè ọsẹ àti omi sí gbogbo àbáwọlé gbogbo ilé ìjọsìn.

Akeredolu ní wípé gbogbo àwọn olùjọ́sìn, àti àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìjọsìn kí wọ́n ó má lo ìbòmú wọn ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ àti tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ, “ó wùn mí láti sọ wípé ìjọba ti ṣe gbogbo ohun tí ó tọ̀ láti lè mójútó àti láti rí dájú wípé gbogbo ìlànà wọ̀nyí wà ní àkọsílẹ̀.

” Tí a bá rí ẹnikẹ́ni, tí ó bá ṣe ìfenú, tí ó bá tàpá sí àwọn òfin ìdènà yìí, a ó ri gẹ́gẹ́ bí ohun ìbàjẹ́ sí àgbègbè,ilé ìjọsìn, Mọ́sálásí, tàbí ilé ìjọsìn kankan tí ó bá tàpá sí òfin yìí,yí ò jẹ́ títìpa ní kíákíá.

Akeredolu sọ́ di mímọ̀ wípé àkọsílẹ̀ àpapọ̀ àwọn tí ó ní ààrùn kòrónà ní ìpínlẹ̀ Òndó jẹ́ mẹ́rìnlélógún, tí mọ́kàndínlógún sì ti gba ìwòsàn, tí méjì sì ti pàdánù ẹ̀mí wọn.

Ó ní wípé àwọn mẹ́ta ni ó wà ní abẹ́ ìtọ́jú, wípé àwọn méjìlélọ́gbọ̀nléníirínwó(432) ni wọ́n ti ṣe àyẹ̀wò ààrùn kòrónà fún.

Ìwé ìròyìn Nation.

Adegbenro Islamiyat

Adegbenro Islamiyat is a Yoruba Language Communication expert. She has a wide experience in writing news, stories and articles in Yoruba language. She also doubles as a Programme presenter and voice over expert. Message her on adegbenroislamiyat74@gmail.com

Leave a Reply

Next Post

Abia govt declares COVID-19 patient wanted after he absconded from isolation center

Thu May 28 , 2020
The Abia State Government has declared one Mr. Emmanuel Ononiwu who tested positive to COVID-19, wanted for refusing to submit himself for appropriate medical management and isolation. The Commissioner for Information, in the State, Chief John Okiyi Kalu, disclosed this in a statement made available to DAILY POST on Thursday. […]
%d bloggers like this: