Warning: sprintf(): Too few arguments in /home/affairst/public_html/wp-content/themes/default-mag/assets/libraries/breadcrumb-trail/inc/breadcrumbs.php on line 254

Alága ẹgbẹ́ òṣèlú APGA ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ Abia

Alága ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Grand Alliance, (APGA), ní ìjọba ìbílẹ̀ Ohafia ní ìpínlẹ̀ Abia, Olóyè Kalu Mba Nwoke, ni ó ti fi ẹgbẹ́ náà sílè tí ó sì lọ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, (APC).

Mba Nwoke, tí ó sọ̀rọ̀ ní Ohafia, ní òpin ọ̀sẹ̀, sọ wípé òhun ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú titun pẹ̀lú àwọn ogọ́run lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ APGA, tí óhún ṣe ìdánilójú wípé bí àwọn ṣe dásẹ̀ wọ inú ẹgbẹ́ APC báyìí, wípé àwọn ẹgbẹ́ PDP àti APGA yí ó di ìgbàgbé pátápátá ní ọdún 2023.

Gẹ́gẹ́ bí alága náà ṣe wí, “mo ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress(APC). Pẹ̀lú bí mo ṣe ṣẹ̀ṣẹ̀ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC yìí, àti pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ gbogbo àwọn obìnrin àti ọkùnrin rere àgbègbè Asaga àti àwọn àgbègbè tí ó kù ní Ohafia, àti àwọn tí ó wà ní inú ẹgbẹ́ òṣèlú APC tẹ́lẹ̀, mo fi hún dá gbogbo ènìyàn lójú wípé ẹgbẹ́ wa titun(APC), yí ó já ewé olúborí ní gbogbo ètò ìdìbò tí óhún bọ̀ lọ́nà ní ìjọba ìbílẹ̀ Ohafia.

Àwọn olóyè àti àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ tí ó jẹ́ ti APC ni ó gba àwọn tí ó wá láti inú ẹgbẹ́ APGA tọwọ́ tẹsẹ̀, tí àwọn olórí APC sì rọ àwọn ènìyàn titun tí ó darapọ̀ mọ́ àwọn kí wọ́n ṣe àmúlò òfin ẹgbẹ́, kí wọ́n sì darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn láti lè mú ìṣe ìjọba gidi wá sí ìmúṣẹ.

Ìwé ìròyìn Daily Post.

Adegbenro Islamiyat

Adegbenro Islamiyat is a Yoruba Language Communication expert. She has a wide experience in writing news, stories and articles in Yoruba language. She also doubles as a Programme presenter and voice over expert. Message her on adegbenroislamiyat74@gmail.com

Leave a Reply

Next Post

Navy arrests 42 suspected cultists during initiation in Cross River

Wed May 27 , 2020
Personnel of the Nigerian Navy Ship Victory have arrested 42 suspected cultists in the Akpabuyo Local Government Area of Cross River State. The suspects, who were handed over to officials of the state government on Tuesday, were allegedly attending an initiation when they were rounded up on Sunday. The Commander […]
%d bloggers like this: