Àwọn mínísítà méjì ti ní ààrùn kòrónà ní orílèdè Chile

Orílèdè Chile ṣe àkọsílẹ̀ àwọn tí ó ní ààrùn kòrónà ní ọjọ́ ajé, pẹ̀lú bí àwọn ẹgbẹ̀rún ènìyàn tí ó ní ààrùn náà láàárín ọjọ́ kan, eléyìí tí àwọn mínísítà méjì tí ó wà lára ìṣe ìjọba Ààrẹ Sebastián Pinera.

Àwọn elétò ìlera ṣe ìkéde àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rinlémárùndínlọ́gọ̀rún(4,895)tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ní ààrùn nà ní apá gúúsù ilẹ̀ orílèdè Amerika, tí wọ́n sì ṣe àkọsílẹ̀ ikú ènìyàn mètàlélógójì.

Mínísítà fún ètò gbogbogbò Alfredo Moreno àti mínísítà fún ètò energy, Juan Carlos Jobet ni wọ́n sọpé àwọn wà lára àwọn tí ó lùgbàdì ààrùn yìí.

“Wòn ti sọ fún mi wípé àyẹ̀wò tí mo ṣe ní ọjọ́ díè sẹ́yìn ti fi ìdi rẹ̀ múlẹ̀ wípé moni ààrùn kòrónà” báyìí ni Moreno kọ sí orí ẹ̀rọ ayélujára túítà rẹ̀, ó ṣe àfikún rẹ̀ wípé òhun kò sì tíì rí àmì kankan tí ó fi hàn.

Mínísítà ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́ta yìí ti fi ara rẹ̀ si ìsémọ́lé lẹ́yìn ìgbàtí àyẹ̀wò fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ ní ààrùn kòrónà.

Àyẹ̀wò fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé Jobet na ní ààrùn kòrónà lẹ́yìn ìgbà tí ó bẹ̀rẹ̀ ìsémọ́lé ní ọjọ́ àbámẹ́ta, “ní ìgbà tí óhún rí àwọn àmì tí ó ní ṣe pẹ̀lú ààrùn kòrónà”, eléyìí ni ohun tí mínísítà fún ètò agbára wí.

Mínísítà ẹni ọdún mẹ́rìnlélógójì “kò súnmọ̀ Ààrẹ Sebastián Pinera tàbí àwọn ènìyàn tí wọ́n jọ hún ṣe ìjọba” ó sọ ọ̀rọ̀ yí láìsọ bí ó ṣe kó ààrùn yìí.

Àwọn mínísítà mẹ́ta míràn, tí wọ́n ti ṣe ara wọn mọ́lé lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti súnmọ́ àwọn tí ó ní ààrùn kòrónà, ni àyẹ̀wò fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé wọn kò ní ààrùn kòrónà tí wọ́n sì ti padà sí ẹnu iṣẹ́ wọn.

Olúǹlú orílèdè Chile ni àfojúsùn àjàkálẹ̀ ààrùn náà, Pẹ̀lú bí ó ṣe jẹ́ wípé púpọ̀ jùlọ nínú àwọn tí ó ní ààrùn kòrónà ní orílèdè Chile ni ó wà ní Olúǹlú tí àpapọ̀ àwọn tí ó ní ní orílèdè náà jẹ́ egbẹ̀rún mẹ́rìnléláàdọ́rin(74,000).

Ní ọ̀sẹ̀ tí ó kọjá,títì pa ni ilé ìgbìmọ̀ asòfin àwọn Sénítọ̀ wà, lẹ́yìn ìgbà tí àyẹ̀wò fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé àwọn Sénítọ̀ mẹ́ta ní ààrùn kòrónà. Orí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ lórí fídíò ni wọ́n ti ṣe ìpàdé.

(AFP).

Adegbenro Islamiyat

Adegbenro Islamiyat is a Yoruba Language Communication expert. She has a wide experience in writing news, stories and articles in Yoruba language. She also doubles as a Programme presenter and voice over expert. Message her on adegbenroislamiyat74@gmail.com

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Next Post

Àwọn méjìdínlógún tí ó ní ààrùn kòrónà ní ìpínlẹ̀ Gombe ni ó kọ̀ láti lo ilé ìyàsótọ̀ ìjọba

Tue May 26 , 2020
Kòju àwọn ọgbọ̀n ènìyàn lọ, ni ó ti yarí wípé àwọn kò fẹ́ ilé ìyàsótọ̀ ìjọba ní ìpínlẹ̀ Gombe. Alága, àwọn ìgbìmọ̀ agbófinró tí óhún rí sí ààrùn kòrónà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Idris Mohammed, ní ọjọ́ ajé ni àwọn ènìyàn méjìlá péré ni òhún le sọ̀rọ̀ nípa wọn, wípé àwọn ìgbìmọ̀ yòókù […]
%d bloggers like this: