Warning: sprintf(): Too few arguments in /home/affairst/public_html/wp-content/themes/default-mag/assets/libraries/breadcrumb-trail/inc/breadcrumbs.php on line 254

Àwọn mẹ́rin pàdánù ẹ̀mí wọn bí ọkọ̀ ofúrufú ṣe já ní pápákọ̀ òfúrufú

Ọkọ̀ òfúrufú àwọn ológun ni ó já ní ọjọ́ ìsẹgun ní pápákọ̀ òfúrufú ní orílèdè Russia, apá ìlà Òòrùn Chukotka, tí ó pa àwọn ènìyàn mẹ́rin tí ó wà nínú ọkọ̀ ofúrufú náà, báyìí ni Gómìnà wí.

Ọkọ̀ òfúrufú àwọn ọmọ ogún Russia ni ó já ní pápákọ̀ òfúrufú tí ó wà ní Chukotka létí Anadyr, tí ó ṣe àpapọ̀ lílò
ológun àti alágbáda.

“Àwọn òṣìṣẹ́ inú ọkọ̀ ofúrufú mẹ́ta, àti òṣìṣẹ́ kan ni ó wà nínú ọkọ̀ ofúrufú. Gbogbo àwọn mẹ́rẹ̀rin ni ó kú,” Gómìnà Roman Kopin kó sí orí ẹ̀rọ ayélujára Instagram rẹ̀.

Àwọn àjọ Russia jẹ́ àbọ̀ wípé ọkọ̀ ofúrufú yìí jẹ́ Mi-8 eléyìí tí óhún ṣe àyẹ̀wò lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n tunse tán.

” Ìdí ìjàmbá náà lè jẹ́ látàrí àtúnṣe tí óhún lọ lọ́wọ́ lórí ọkọ̀ ofúrufú náà,”ÀWỌN àjọ oníròyìn TASS ni ó gba ọ̀rọ̀ sílè lénu ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun tí ó sọ̀rọ̀.

Wọ́n pín àwọn olùse ìwádìí ológun sí ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹlẹ̀, báyìí ni ó sọ.

(AFP).

Adegbenro Islamiyat

Adegbenro Islamiyat is a Yoruba Language Communication expert. She has a wide experience in writing news, stories and articles in Yoruba language. She also doubles as a Programme presenter and voice over expert. Message her on adegbenroislamiyat74@gmail.com

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Next Post

We are loyal to Buhari, says Nigerian Air Force

Tue May 26 , 2020
Nigeria’s Chief of Air Staff, Air Marshal Abubakar Sadique, has said that the Air Force is loyal to President Muhammadu Buhari. He spoke at Eid-el-Fitr Luncheon organised with troops in the North East on Monday in Yola. The CAS was represented by Air Commodore Muhammed Yusuf, Commander 153 Base Services […]
%d bloggers like this: