Àwọn méjìdínlógún tí ó ní ààrùn kòrónà ní ìpínlẹ̀ Gombe ni ó kọ̀ láti lo ilé ìyàsótọ̀ ìjọba

Kòju àwọn ọgbọ̀n ènìyàn lọ, ni ó ti yarí wípé àwọn kò fẹ́ ilé ìyàsótọ̀ ìjọba ní ìpínlẹ̀ Gombe.

Alága, àwọn ìgbìmọ̀ agbófinró tí óhún rí sí ààrùn kòrónà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Idris Mohammed, ní ọjọ́ ajé ni àwọn ènìyàn méjìlá péré ni òhún le sọ̀rọ̀ nípa wọn, wípé àwọn ìgbìmọ̀ yòókù ni yó sọ nípa bí àwọn méjìdínlógún yòókù ṣe rin ìrìn wọn tí wọ́n fi kọ ìtọ́jú ilé ìyàsótọ̀ ìjọba sílè.

Ó ní “A ní àkójọpọ̀ àwọn ọgbọ̀n ènìyàn tí a fẹ́ dá padà sí ìlú wọn, lára wọn ni àwọn ọmọ Adamawa márùn;a gba ẹ̀jẹ̀ wọn sílè, wọ́n sì ti padà sí ìlú wọn, àwọn nìkan ni àwọn tí ó ní ààrùn kòrónà ní ìpínlẹ̀ Gombe, ṣùgbọ́n ní ti òtítọ́ wọ́n ti padà sí Adamawa.

” Àwọn méjì yòókù jẹ́ ọmọ ìpínlẹ̀ Kánò, tí wọ́n sì ti wà ní ilé ìwòsàn ìyàsótọ̀ ní, ẹnìkan ti ìpínlẹ̀ Ògùn, ẹnìkan ti ìpínlẹ̀ Nassarawa, ìkan láti ìpínlẹ̀ Borno, tí a sì ti dá wọn padà sí ìpínlẹ̀ wọn.

” Nínú àwọn ogún ènìyàn tí ó kù,ni àwọn tí àhún kojú ìṣòro láti dá wọn padà sí ìpínlẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n àhún sa gbogbo ipá wa .Ní ọjọ́ àìkú, a tún dá méjì padà. Bí púpọ̀ nínú wọn kò ṣe fẹ́ wá, wọ́n sì wà ní ìyàsótọ̀, wọn kò jáde sí gbangba ṣùgbọ́n àwọn gbogbo àwọn ọba, àti àwọn olórí olóṣèlú ni ó fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn láti ríi dájú wípé wọ́n padà sí ìlú wọn, wọ́n tọ́jú wọn, tí wọ́n sì tú wọn sílè ní ìgbà tí ó tọ́.

Adegbenro Islamiyat

Adegbenro Islamiyat is a Yoruba Language Communication expert. She has a wide experience in writing news, stories and articles in Yoruba language. She also doubles as a Programme presenter and voice over expert. Message her on adegbenroislamiyat74@gmail.com

Leave a Reply

Next Post

Three dead in Lagos-Ibadan Expressway accident

Tue May 26 , 2020
The Federal Road Safety Corps in Ogun State said three persons died while 14 others sustained injuries in two separate accidents along Lagos-Ibadan Expressway on Monday. FRSC state Sector Commander, Mr Clement Oladele, gave the details in a statement made available to News Agency of Nigeria in Ota. Oladele explained […]
%d bloggers like this: