Warning: sprintf(): Too few arguments in /home/affairst/public_html/wp-content/themes/default-mag/assets/libraries/breadcrumb-trail/inc/breadcrumbs.php on line 254

Ìjọba orílèdè Namibia ṣe ìdínà mọ́ ríra ọkọ̀ fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba títí di ọdún 2025

Ààrẹ orílèdè Namibia ni ó pàṣẹ ìdínà mọ́ ríra ọkọ titun fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, àwọn olóṣèlú tí ó wà ní ipò gíga ní ọjọ́ ọ̀jọ́bọ, láti lè rí owó láti lè kojú àjàkálẹ̀ ààrùn kòrónà, báyìí ni ó wí.

Ààrẹ Hage Geingob”ti pàṣẹ wípé àwọn kò ní ra ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́ titun fún ìjọba orílèdè Namibia láti ọdún 2020 títí di ọdún 2025″,abenugan Ààrẹ Alfredo Hengari ni ó ṣe ìkéde yìí nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀.

“kò sí ríra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ titun fún gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kankan, tàbí àwọn olórí ìjọba ní orílèdè Namibia”.

Ó ní ìpinu yìí, yí ó ran àwọn lọ́wọ́ láti lè ṣe ìpamọ́ igba míllíònù dọ́là Namibia(Us$10.7million),eléyìí tí àwọn máa lò fún àwọn ǹkan pàjáwìrì tó ṣe pàtàkì, pápá julọ ní irú àkókò tí orílèdè ń kojú àisedédé pẹ̀lú ètò ìlera àti ètò ọrọ̀ ajé látàrí àjàkálẹ̀ ààrùn kòrónà”.

Apá Gúúsù orílèdè Áfíríkà ti ènìyàn míllíònù méjì àti àbọ̀(2.5million) ni ó ti ṣe àkọsílẹ̀ ènìyàn mẹ́rìndínlógún tí ó ní ààrùn kòrónà, láìsí àkọsílẹ̀ ikú kankan.

Àwọn mínísítà, orílèdè Namibia àti àwọn Igbákejì ni ó ní ẹ̀tọ́ sí ọkọ̀ mẹ́sídísì ayọ́kẹ́lẹ́ látàrí ipò tuntun wọn.

Ààrẹ tún pàṣẹ wípé kí wọ́n dín epo rọ̀bì tí àwọn olórí olóṣèlú ń lò ní ososù kù,báyìí ni Ààrẹ wí.

Ní ọdún 2002,Ààrẹ ìgbánà Sam Nujoma ti gbẹ́sẹ̀ lé lílo ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mẹ́sídísì, ó ní dandan kí àwọn mínísítà kó máa wa ọkọ̀ Toyota Camry.

Ìròyìn Nàíjíríà.

Adegbenro Islamiyat

Adegbenro Islamiyat is a Yoruba Language Communication expert. She has a wide experience in writing news, stories and articles in Yoruba language. She also doubles as a Programme presenter and voice over expert. Message her on adegbenroislamiyat74@gmail.com

Leave a Reply

Next Post

EFCC hands over ‘Diezani’ building to Lagos for isolation centre

Fri May 15 , 2020
The Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), yesterday handed over a three-storey residential building forfeited by former Minister of Petroleum Resources, Diezani Allison-Madueke to the Lagos State government for use as a COVID-19 isolation centre. The property comprising six flats of three bedrooms and a boys’ quarter was forfeited by […]
%d bloggers like this: