Warning: sprintf(): Too few arguments in /home/affairst/public_html/wp-content/themes/default-mag/assets/libraries/breadcrumb-trail/inc/breadcrumbs.php on line 254

Àwọn agbénipa ṣe ikú pa ọkùnrin ògboni kan ní ìpínlẹ̀ Òndó

Ọwọ́ àwọn olọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo ti tẹ àwọn ènìyàn méjì tí ó mọ̀ nípa pípa olórí àwọn ògboni,Olóyè Stephen Akinwunmi, ní Ọrẹ, ìjọba ìbílẹ̀ Odigbo.

Akinwunmi, ẹni tí ó jẹ́ olórí fún àwọn ògboni ní apá gúúsù-iwọ̀òrùn, ni wọ́n ṣe ikú pa ní agbègbè ilé ìtura Saint Stephen, Ọ̀rẹ̀, ní ọjọ́ ọ̀jọ́bọ.

Àkòjopọ̀ ìròyìn fi múlẹ̀ wípé wọ́n yin ìbọn fún arákùnrin yìí, ní ìgbàtí ó kọ̀ láti tẹ̀lé àṣẹ tí àwọn agbénipa pa fún wípé kí ó wọlé sínú ọkọ̀.

Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n pá tán, àwọn agbénipa wọ̀nyí wa ọkọ̀ jáde kúrò nínú ilé ìtura lọ sí ibi tí ẹnikẹ́ni kò mọ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ṣe sọ, ó ní :àwọn ìwé kan àti àwọn ǹkan mìíràn, pẹ̀lú míllíònù méjì náírà, tí ó jẹ́ ti olóògbé, ni àwọn agbénipa yìí ti kó lọ.

Àbúrò olóògbé, Ọ̀gbeni Joshua Akindele, sọ wípé àwọn agbénipa yìí ti wà ní ilé ìtura yìí láti bí ọjọ́ mẹ́ta kí wọ́n tó ṣe ikú pa Olóyè Stephen.

Aya olóògbé, Toyin rọ ìjọba Ìpínlẹ̀ àti àwọn ètò alábòò láti dá àbò bo àwọn mòlẹ̀bí òhun, nítorí wípé òhún tí hún gba orisiris àtẹ̀jísẹ́ tí ò ní ṣe pẹ̀lú ìbẹ̀rùbojo láti ọ̀dọ̀ ẹni tí òhun kò dámọ̀.

Òṣìṣẹ́ ìbátan gbogbo ènìyàn ti àwọn olọ́pàá ní ìpínlẹ̀ náà, Ọ̀gbẹni Tee-Leo Ìkorò, tí ó fi ìdi rẹ̀ múlẹ̀ wípé ọwọ́ sìkún agbófinró tite àwọn méjì kan, wípé ikọ̀ àwọn olọ́pàá sì tún tẹ̀síwájú nínú ìwádi wọn.

“Àhún sa ipá láti rí àwọn ọ̀daràn yìí, a máa ríi dájú wípé ọwọ́ pálábá wọ́n ségi” báyìí ni Ìkorò wí.

Ìwé ìròyìn punch.

Adegbenro Islamiyat

Adegbenro Islamiyat is a Yoruba Language Communication expert. She has a wide experience in writing news, stories and articles in Yoruba language. She also doubles as a Programme presenter and voice over expert. Message her on adegbenroislamiyat74@gmail.com

Leave a Reply

Next Post

Ìjọba orílèdè Namibia ṣe ìdínà mọ́ ríra ọkọ̀ fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba títí di ọdún 2025

Fri May 15 , 2020
Ààrẹ orílèdè Namibia ni ó pàṣẹ ìdínà mọ́ ríra ọkọ titun fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, àwọn olóṣèlú tí ó wà ní ipò gíga ní ọjọ́ ọ̀jọ́bọ, láti lè rí owó láti lè kojú àjàkálẹ̀ ààrùn kòrónà, báyìí ni ó wí. Ààrẹ Hage Geingob”ti pàṣẹ wípé àwọn kò ní ra ọkọ […]
%d bloggers like this: