Ìyá àti ọmọ ní ààrùn kòrónà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀sun

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀sun ti kéde ènìyàn méjì tí ó ní ààrùn kòrónà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀sun,tí ó mú kí àpapọ̀ àwọn tí ó ní ààrùn kòrónà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀sun jẹ́ mẹ́wàá.

Kọmísọ́nà fún ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ Ọ̀sun,Dókítà Rafiu Isamotu, ní orí ẹ̀rọ ayélujára túítà ní ọjọ́ àìkú ni ó sọ di mímọ̀ wípé ìyàwó,àti ọmọ ọkàn lára àwọn tí ó ní ààrùn kòrónà tẹ́lẹ̀.

Dókítà Isamotu sọ wípé, “bósé ń lọ lórí ààrùn kòrónà,ọjọ́ kẹta oṣù karùn-ún, ọdún tí awàyí :a tún ti rí àwọn méjì míràn tí ó ní ààrùn kòrónà ní òní,ìyàwó àti ọmọ ọkàn nínú àwọn tí ó ní ààrùn kòrónà tẹ́lẹ̀.Àpapọ̀ àwọn tí ó ní ààrùn kòrónà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀sun jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n(36),àwọn tí ó ní jẹ́ mẹ́wàá(10),àwọn tí ó kú jẹ́ mẹ́ta(3),àwọn tí wọ́n ti dá sílè jẹ́ mẹ́tàlélógún(23).

Ní ìgbàtí a ṣe ìwádìí síwájú,Dókítà Rafiu sọ fún àwọn oníròyìn wípé àwọn méjì yìí jẹ́ lára àwọn tí ìpínlẹ̀ fi ẹ̀jẹ̀ wọn ránsẹ́ fún àyẹ̀wò.

Ìjọba Ìpínlẹ̀,ní òpin ọ̀sẹ̀,ṣe àkọsílẹ̀ ikú ènìyàn kẹta tí ó jẹ́ ẹni ọmọ ọdún ọgọ́ta ọdún tí ó wà ní ilé ìwòsàn ìyàsótọ̀ Asubiaro, Osogbo.

Isamotu sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ àbámẹ́ta, “Pẹ̀lú ìbànújẹ́, a pàdánù ọkàn lára àwọn tóní ààrùn kòrónà tí ó jẹ́ ẹni ọmọ ọdún ọgọ́ta tí ó wà ní ilé ìwòsàn ìyàsótọ̀ ní Òsogbo.A gba ní àdúrà wípé kí Ọlọhun tẹ́ ẹ sí afẹ́fẹ́ rere, kí ó sì mú àwọn ẹbí rẹ̀ ní àyà le.

Ìwé ìròyìn Punch

Adegbenro Islamiyat

Adegbenro Islamiyat is a Yoruba Language Communication expert. She has a wide experience in writing news, stories and articles in Yoruba language. She also doubles as a Programme presenter and voice over expert. Message her on adegbenroislamiyat74@gmail.com

Leave a Reply

Next Post

Asòfin kan kú ní ìpínlẹ̀ Nassarawa látàrí ààrùn kòrónà

Sun May 3 , 2020
Òkan lára àwọn asòfin tí óhún sojú àrin gbùngbùn ìpínlẹ̀ Nassarawa ní ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ Nassarawa,Ọ̀gbẹni Sule Adamu, tí kú látàrí ààrùn kòrónà. Gómìnà ìpínlè náà Abdullahi Sule, ni ó sọ di mímọ̀ ní ọjọ́ àìkú ní ìgbàtí óhún bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀. Ó ní ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ […]
%d bloggers like this: