Àwọn ọmọ méjì ti ní ààrùn kòrónà ní ìpínlẹ̀ Enugu

Àjọ tóhún rísí ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ Enugu ni ó ti ṣe àkọsílẹ̀ ènìyàn mẹ́rin tí ó ní ààrùn kòrónà.

Nínú ohun tí komísónà fún ètò ìlera, Dókítà Ikechukwu Obi, sọ ní alẹ́ ọjọ́ àbámẹ́ta, ní kété tí àwọn àjọ tí óhún mójútó àjàkálẹ̀ ààrùn ní orílèdè Nàíjíríà(NCDC)ṣe ìkéde tán,ni ó sọ wípé wọ́n ti rí àwọn mẹ́rin tí ó ní ààrùn kòrónà, tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà méjì àti màjèsín méjì.

Dókítà Obi sọ wípé, “Àwọn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ní yìí, jẹ́ ọmọ ìpínlẹ̀ Bauchi, ṣùgbọ́n wọn hún gbé ní ìpínlẹ̀ Enugu”.

“Wọ́n rin ìrìn àjò lọ sí Jos, ní ìpínlẹ̀ Plateau, pẹ̀lú enìkẹta tí ò ní ààrùn kòrónà ní ìpínlẹ̀ Enugu”.

“Eléyìí jẹ́ kí àpapọ̀ àwọn tí ó ní ààrùn kòrónà ní ìpínlẹ̀ Enugu jẹ́ mẹ́fà(6)”.

Kọmísọ́nà fún ètò ìlera, ní báyìí rọ gbogbo àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Enugu láti máa ṣe àmúlò àwọn ohun ìdènà láti dẹ́kun ìtànkalẹ̀ àjàkálẹ̀ ààrùn kòrónà tí àwọn àjọ tí óhún mójútó àjàkálẹ̀ ààrùn ní orílèdè Nàíjíríà(NCDC).

Ìwé ìròyìn punch.

Adegbenro Islamiyat

Adegbenro Islamiyat is a Yoruba Language Communication expert. She has a wide experience in writing news, stories and articles in Yoruba language. She also doubles as a Programme presenter and voice over expert. Message her on adegbenroislamiyat74@gmail.com

Leave a Reply

Next Post

BREAKING: Revenue collector shot dead in Warri

Sun May 3 , 2020
A revenue collector, identified simply as Mr. London was reportedly shot dead by suspected assassins at the Warri Main Garage, Warri South council area of Delta state. The incident it was gathered happened at about 5pm on Sunday. It was gathered the deceased was just recovering from bullet injuries sustained […]
%d bloggers like this: