0 0
Read Time:1 Minute, 16 Second

olórí ilẹ̀ Guinea-Bissau,Nuno Nabian, àti àwọn míràn ni àyẹ̀wò fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé wọ́n ní ààrùn kòrónà,àwọn àjọ oníròyìn Lusa ni ó sọ́ di mímọ̀ ní ọjọ́ ojọ́rú.

Nabian àti àwọn bí i kòju mẹ́ta lọ nínú ìṣe ìjọba rẹ̀ ni ó ti ní ààrùn yìí,Lusa ṣe àkọsílẹ̀ ní ìgbàtí mínísítà fún ètò ìlera, Antonio Deuna,hún sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ amóhùn máwòrán.

Ẹnìkan lára àwọn tí ó wà ní ìjọba ni ó sọ fún Lusa wípé àwọn yòókù tí wọ́n ní ààrùn kòrónà ni mínísítà fún ètò abẹ́lé Botche Cande àti àwọn akọ̀wé ìpínlẹ̀ méjì,Mario Fambe àti Monica Buaro.

“Àwọn tí ó ní yìí jẹ́ alásùnmọ́ọ́ ọ̀gá àgbà mínísítà fún ètò abẹ́lé tí ó ti fi ilẹ̀ boora” báyìí ni Lusa wí.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn ájọ tí óhún rí sí ètò àjàkálẹ̀ ààrùn ní ilẹ̀ Áfríkà ṣe sọ ní ọjọ́ ojọ́rú, “Guinea-Bissau ti ṣe àkọsílẹ̀ ènìyàn mẹ́tàléláàdórin(73) tí ó ní ààrùn kòrónà,tí ènìyàn kan sì ti kú”

Orílèdè kéréje yìí,tí àwọn ènìyàn tí ó wà ní bẹ̀ koju bíi míllíònù kan lé ní ẹgbẹ̀rin(1.8m),ni àmọ́ sí ọkàn lára àwọn ìlú tí ó ní àyípadà ní ilẹ̀ Áfríkà,pelu ìyípọ̀ àwọn ológun láti gba ìjọba bíi ẹ̀mẹrìndínlógún,láti ìgbà tí ìlú náà ti gba òmìnira ní ọdún 1974,eléyìí tí mẹ́rin sì yọrí.

Láti inú oṣù kejì ni Nabian ti bẹ̀rẹ̀ ìsèjọba.

About Post Author

Adegbenro Islamiyat

Adegbenro Islamiyat is a Yoruba Language Communication expert. She has a wide experience in writing news, stories and articles in Yoruba language. She also doubles as a Programme presenter and voice over expert. Message her on adegbenroislamiyat74@gmail.com
Happy
Happy
0 %
Sad
Sad
0 %
Excited
Excited
0 %
Sleepy
Sleepy
0 %
Angry
Angry
0 %
Surprise
Surprise
0 %

Average Rating

5 Star
0%
4 Star
0%
3 Star
0%
2 Star
0%
1 Star
0%

Leave a Reply