Warning: sprintf(): Too few arguments in /home/affairst/public_html/wp-content/themes/default-mag/assets/libraries/breadcrumb-trail/inc/breadcrumbs.php on line 254

Ìjọba àpapọ̀ Orílèdè ti kéde ọjọ́ etì,ọjọ́ kíní oṣù karùn-ún fún ọludé gbogbogboo

Ìjọba àpapọ̀ Orílèdè ti kéde ọjọ́ kíní oṣù karùn-ún,fún ọludé gbogbogboo,láti ṣe ayẹyẹ ọdún àwọn òṣìṣẹ́ káàkiri orílèdè Nàíjíríà.

Mísítà fún ètò abẹ́lé,Rauf Aregbesola,tí ó kéde oludé yìí nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀,ni ó kí àwọn òṣìṣẹ́ orílèdè Nàíjíríà kú sùúrù,ìtẹ̀mọra,àti àgbọ́yé wọn pàápàá jùlọ,ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wọn pẹ̀lú akitiyan ìsèjọba Ààrẹ Buhari láti dẹ́kun ìtànkálẹ̀ àjàkálẹ̀ ààrùn kòrónà ní orílèdè.

Aregbesola wípé sùúrù tí àwọn òṣìṣẹ́ ní yìí yí ó ran gbogbo akitiyan àwọn ìjọba àti àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti lè tètè fi òpin sí ìtànkalẹ̀ àjàkálẹ̀ ààrùn náà.

Ó ní pẹ̀lú ìfowópamọ́ gbogbo àwọn ọmọ orílèdè, àti pẹ̀lú ṣíṣe àmúlò gbogbo àwọn ìdènà tí àwọn àjọ elétò ìlera sọ,wípé gbogbo ohun tí wọ́n hún kojú látàrí ààrùn yìí máa tó dópin.

Mínísítà sọ wípé ètò ajé orílèdè náà yí ó padà bọ̀ sí ipò lẹ́yìn àjàkálẹ̀ ààrùn kòrónà.

Ìwé ìròyìn Guardian

Adegbenro Islamiyat

Adegbenro Islamiyat is a Yoruba Language Communication expert. She has a wide experience in writing news, stories and articles in Yoruba language. She also doubles as a Programme presenter and voice over expert. Message her on adegbenroislamiyat74@gmail.com

Leave a Reply

Next Post

olórí ilẹ̀ Guinea-Bissau, àwọn mẹ́ta míràn ni àyẹ̀wò fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé wọ́n ní ààrùn kòrónà

Thu Apr 30 , 2020
olórí ilẹ̀ Guinea-Bissau,Nuno Nabian, àti àwọn míràn ni àyẹ̀wò fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé wọ́n ní ààrùn kòrónà,àwọn àjọ oníròyìn Lusa ni ó sọ́ di mímọ̀ ní ọjọ́ ojọ́rú. Nabian àti àwọn bí i kòju mẹ́ta lọ nínú ìṣe ìjọba rẹ̀ ni ó ti ní ààrùn yìí,Lusa ṣe àkọsílẹ̀ ní […]
%d bloggers like this: