Warning: sprintf(): Too few arguments in /home/affairst/public_html/wp-content/themes/default-mag/assets/libraries/breadcrumb-trail/inc/breadcrumbs.php on line 254

Afolabi Ibrahim ṣe àjọyọ̀ ọjọ́ ìbí gbajúgbajà olórin takasufe Qudus Fakoya(Qdot)

Afolabi Ibrahim ni ó ṣe àjọyọ̀ ọdún ọjọ́ ìbí pẹ̀lú gbajúgbajà akọrin tàkasúfé Qudus Fakoya(Qdot).

Nínú ọ̀rọ̀ tí ó bá ilé isẹ́ Affairstv sọ ní ọjọ́ ọ̀jọ́bọ ni ó ti sọ di mímọ̀.

Ó ṣe àpèjúwe Qdot gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ní ọkàn rere sí gbogbo ènìyàn tí ó sì féràn láti máa ràn ọmọlàkejì lọ́wọ́,ó ní ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkàìkàtán ìrànlọ́wọ́ fún ohun,pé kì sì ṣe òhun nìkan o.

Ó ní akọrin yìí rí gbogbo ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ àti ọmọ ìyarẹ̀ ni,ó ní gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ni ó ní ìwà dáadáa yìí, kódà ayàwòrán rẹ pẹ̀lú ẹni tí óhún má báse fídíò.

Ó ní Qdot féràn láti máa ṣe àpọ́nlé ènìyàn púpọ̀,ó ní kò fi orúkọ òhun pé òhun rí, wípé bẹ́ẹ̀ sì ni ó má hún hu ìwà sí gbogbo ènìyàn.

Ó ní láti ọjọ́ tí óhún ti mọ Qdot, wípé kò bínú rí,ó ní gbogbo ọ̀nà tó bá mọ̀ láti fi ran ènìyàn lọ́wọ́ ni ó má ń ṣe.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Afolabi sọ pé ;

“Bí o ṣe ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí yìí ò ní mọ ìbànújẹ́ bó ti wulẹ̀ kó kéré mọ,Ọlọ́run á máa ṣe alábò rẹ, kí Ọlọ́run túbọ̀ máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ si ní òní àti títí láíláí”

Adegbenro Islamiyat

Adegbenro Islamiyat is a Yoruba Language Communication expert. She has a wide experience in writing news, stories and articles in Yoruba language. She also doubles as a Programme presenter and voice over expert. Message her on adegbenroislamiyat74@gmail.com

Leave a Reply

Next Post

JUST IN: Russian Prime Minister tests positive for COVID-19

Thu Apr 30 , 2020
Russian Prime Minister Mikhail Mishustin has tested positive for coronavirus (COVID-19). Mishustin on Thursday informed President Vladimir Putin that he had been diagnosed with the new coronavirus and will be temporarily stepping down to recover. Mishustin, 54, suggested that First Deputy Prime Minister Andrei Belousov serve as acting prime minister […]
%d bloggers like this: