Warning: sprintf(): Too few arguments in /home/affairst/public_html/wp-content/themes/default-mag/assets/libraries/breadcrumb-trail/inc/breadcrumbs.php on line 254

Ìpínlẹ̀ Ọ̀sun ṣe àkọsílẹ̀ ènìyàn méjìlá titun tó ní ààrùn kòrónà

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀sun ti ṣe ayẹwo fún mẹ́tàdínláàdọ́san ènìyàn,tí méjìlá nínú wọn dẹ̀ ní ààrùn kòrónà.

Kọmísọ́nà fún ètò ìlera,Dókítà Rafiu Isamotu ní ó sọ di mímọ̀ nínú ọ̀rọ̀ tí ó sọ ní ọjọ́ àbámẹ́ta,ni ó ti sọ wípé ní Òsogbo,Ifè,Ede,Ikire àti Èjìgbò ni àwọn ti rí àwọn ènìyàn méjìlá yìí.

Dókítà Isamotu sọ wípé nínú ìsémọ́lé ọ̀sẹ̀ méjì àkọ́kọ́ ṣe ni wọ́n ṣe àyẹ̀wò yìí.

Ó ní pẹ̀lú méjìlá yìí,ni ó mú àpapọ̀ àwọn tí ó ní jẹ́ mẹ́tàlá ní ìpínlẹ̀ Ọ̀sun.

Kọmísọ́nà rọ gbogbo àwọn ọmọ Ọ̀sun láti má kó àárẹ̀ ọkàn,ṣùgbọ́n láti túbọ̀ máa tẹ̀lé òfin kónílégbélé tí ìjọba ṣe,kí wọ́n máa ṣe ìjìnà sí ara ẹni ní àwùjọ, kí wọ́n sì ma ṣe àmúlò gbogbo ìdènà láti lè dẹ́kun ìtànkálẹ̀ ààrùn kòrónà.

Ilé ìròyìn Ọ̀sun

Adegbenro Islamiyat

Adegbenro Islamiyat is a Yoruba Language Communication expert. She has a wide experience in writing news, stories and articles in Yoruba language. She also doubles as a Programme presenter and voice over expert. Message her on adegbenroislamiyat74@gmail.com

Leave a Reply

Next Post

BREAKING: Obaseki appoints 38-year-old Uzamere as new Chief of Staff

Sat Apr 25 , 2020
Edo State Governor, Godwin Obaseki, has approved the appointment of Osaze Ethan Uzamere, as his Chief of Staff. In a statement, Secretary to the State Government, Osarodion Ogie, said the appointment takes immediate effect. Osaze is the son of Senator Ehigie Uzamere, who represented Edo South Senatorial District in the […]
%d bloggers like this: