Wọ́n pa àwọn Olọ́pàá méjì ní ilé isẹ́ Àtíkù

Àwọn olọ́pàá méjì ti pàdánù èmi wọn ní ìpínlẹ̀ Adamawa.

Àwọn olọ́pàá yìí ni DSP Gbenga,Asp Yohanna,ni wọn pa ní RicoGado,ilé isẹ́ Igbákejì ààre àná Atku Abubakar,tí wọ́n tí hún ṣe oúnjẹ àwọn ẹranko.

Wọ́n ní àwọn apànìyàn ni ó pa wọ́n ní ìgbàtí wọ́n lọ ṣe àbẹ̀wo ibi tí wọ́n fẹ fi àwọn ọdẹ sí ní ilé isẹ́ RicoGado.

Agbófinró kan,tí ó sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà,ní ó sọ wípé òhún gbàgbọ́ wípé wọ́n sọ́ àwọn olọ́pàá yìí pa ni.

Ó ní wípé”wọ́n lọ sí RicaGado láti lọ wo ibi tí àwọn ènìyàn àwọn fẹ́ máa dúró sí,wípé àwọn olùsọ sọ wípé kí àwọn jọ dé ibì kan;bẹ́ẹ̀ni ẹnìkan yin ìbon mọ́ àwọn agbófinró yìí.

Abenugan fún àgọ́ olọ́pàá ìpínlẹ̀ náà,DSP Suleiman Nguroje,ni ó fi ikú àwọn olọ́pàá yìí múlẹ̀.

Ó ní wípé:”Bẹ́ẹ̀ni,mo lè fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé wọ́n ti pa méjì nínú àwọn ènìyàn wa ASP àti DSP, ṣùgbọ́n ní ti ẹni tí ó pa wọ́n,tàbí ibi tí wọ́n ti pa wọ́n, ni mi ò tí mọ̀ báyìí.

” lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí,òkú wọn wà pẹ̀lú wa,tí a sì hún dúró láti mọ bí wọ́n ṣe kú”bayii ni ó wí.

Ìwé ìròyìn punch.

Adegbenro Islamiyat

Adegbenro Islamiyat is a Yoruba Language Communication expert. She has a wide experience in writing news, stories and articles in Yoruba language. She also doubles as a Programme presenter and voice over expert. Message her on adegbenroislamiyat74@gmail.com

Leave a Reply

Next Post

Ilé ejọ́ ní kí àwọn òjísẹ́ Ọlọ́run tí ó tàpá sí òfin kónílégbélé san owó ìtanràn ìdajì míllíònù

Wed Apr 22 , 2020
Ilé ejọ́ ní Adó-Ekiti ni ó gbésẹ̀ àwọn òjísẹ́ Ọlọ́run méjì ní ọjọ́ ìsẹgun,Abiodun Daramola àti Sunday Sunday Akinwande,fún rírú òfin kónílégbélé tí ìjọba Ìpínlẹ̀ náà ṣe. Adájọ́ ilé ejọ́ náà,Mr Lanre Owoleso,eléyìí tí ó ní àwọn òjísẹ́ méjì yìí jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kànwọ́n,ni ó pawọ́n ní àṣẹ […]
%d bloggers like this: