Warning: sprintf(): Too few arguments in /home/affairst/public_html/wp-content/themes/default-mag/assets/libraries/breadcrumb-trail/inc/breadcrumbs.php on line 254

Ìpínlẹ̀ Borno ṣe àkọsílẹ̀ ikú ènìyàn míràn látàrí ààrùn kòrónà

Ní ọjọ́ ojọ́rú,ni ìjọba ìpínlẹ̀ Borno kéde ikú ẹnì kejì tí kòrónà pa.

Igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Borno, Alhaji Umar Kadafur,ẹni tí ó tún jẹ́ alága ìgbìmọ̀ ńlá lórí ààrùn kòrónà ní ìpínlẹ̀ naa ni ó sọ́ di mímọ̀ ní ọjọ́ ojọ́rú ní ìgbàtí óhún jábọ̀ lórí ààrùn kòrónà ní ìpínlẹ̀ náà.

“Ọmọ ìlú Biu ni ẹni tí ó kú, tí wọ́n sì ti hún wá àwọn tí wọ́n ti jọ wà papọ̀”.

“Ọ̀kan lára àwọn tí ó ti jọ wà ni oníṣòwò ni ọjà ìlu Biu,láti lè tẹ́lẹ̀ òfin,ìjọba Ìpínlẹ̀ náà ti pàṣẹ tí ti ọjà yìí pa fún fífín.

” Ní òní,ẹ́rìnlélógóje ènìyàn ni wọ́n ti rí,tí wọ́n sì ti ṣe àyẹ̀wò fún máàrúndínlọ́gọ́ta níbè,tí àwọn mẹ́san nínú wọn sì ní ààrùn kòrónà,pẹ̀lu àwọn méjì tí wọ́n kú”, báyìí ni ó wí.

Ó rọ gbogbo àwọn ènìyàn láti máa ṣe àmúlò gbogbo ìdènà láti dẹ́kun ìtànkalẹ̀ àjàkálẹ̀ ààrùn kòrónà eléyìí tí àwọn tí ó mọ̀ nípa rẹ̀ sọ fún wọn.

NAN ṣe ìjábọ̀ wípé ẹni àkọ́kọ́ tí ó kú yí jẹ́ nọ́ọ̀sì,tí ó kú sí ilé ìwòsàn ilé ìwé Fáṣítì Maiduguri ní ọjọ́ àbámẹ́ta.

NAN jábọ̀ wípé láti tẹ̀lé atọ́ka ààrùn kòrónà yìí ní Borno, Gómìnà Babagana Zulum ti pàṣẹ ìsémọ́lé ọ̀sẹ̀ méjì ní ìpínlẹ̀ náà ní ọjọ́ ojọ́rú.

Zulum,ẹni tí ó ṣe ìpolongo nínú ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ní Maiduguri ní ọjọ́ ajé,síbẹ̀síbẹ̀, ó ní wípé ìsémọ́lé kò ni kan àwọn òṣìṣẹ́ pàtàkì.

(NAN)

Adegbenro Islamiyat

Adegbenro Islamiyat is a Yoruba Language Communication expert. She has a wide experience in writing news, stories and articles in Yoruba language. She also doubles as a Programme presenter and voice over expert. Message her on adegbenroislamiyat74@gmail.com

Leave a Reply

Next Post

<em>Àwọn Òṣìṣẹ́ Elétò Ìlera tí wọ́n hún ṣe àyẹ̀wò ààrùn kòrónà bẹ̀rẹ̀ ìya</em>n Isẹ́lódì ní Kánò

Wed Apr 22 , 2020
Àyè tí wọ́n pèsè fún ṣíṣe àyẹ̀wò ààrùn kòrónà ti da iṣẹ́ lẹ̀. Olùdarí àjọ tí óhún ṣe ìwádi àjàkálẹ̀ ààrùn ní ilé ìwòsàn Aminu Kano(AKTH),Isah Abubakar ni ó sọ́ di mímọ̀ fún ilé isẹ́ amóhùn máwòrán channels ní ọjọ́ ojọ́rú ni ó sọ wípé èlò ìṣe àyẹ̀wò ti tán. […]
%d bloggers like this: