Warning: sprintf(): Too few arguments in /home/affairst/public_html/wp-content/themes/default-mag/assets/libraries/breadcrumb-trail/inc/breadcrumbs.php on line 254

Ilé ejọ́ ní kí àwọn òjísẹ́ Ọlọ́run tí ó tàpá sí òfin kónílégbélé san owó ìtanràn ìdajì míllíònù

Ilé ejọ́ ní Adó-Ekiti ni ó gbésẹ̀ àwọn òjísẹ́ Ọlọ́run méjì ní ọjọ́ ìsẹgun,Abiodun Daramola àti Sunday Sunday Akinwande,fún rírú òfin kónílégbélé tí ìjọba Ìpínlẹ̀ náà ṣe.

Adájọ́ ilé ejọ́ náà,Mr Lanre Owoleso,eléyìí tí ó ní àwọn òjísẹ́ méjì yìí jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kànwọ́n,ni ó pawọ́n ní àṣẹ wípé kí ènìyàn kọ̀ọ̀kan san owó ìtanràn ìdajì míllíònù, kí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ ìlú fún wákàtí kan.

Ẹ̀sùn tí wọn fi kan àwọn òjísẹ́ méjèèjì yìí ni wípé wọ́n ṣe àkójọ àwọn ènìyàn tí ó ju ọgbọ̀n lọ nínú ilé ìjọsìn ní ọjọ́ àìkú, eléyìí tí ó tako òfin tí ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkìtì fi lọ̀ọ̀lẹ̀(kò sí àwùjọ tí ó gbọdọ̀ kọjá ènìyàn ogún).

Agbejọ́rò fún ìpínlẹ̀ náà, Ọ̀gbẹni Fẹmi Onipede,sọ fún ilé ejọ́ wípé “àwọn òjísẹ́ yìí ṣẹ ẹsẹ náà ní ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù kẹrin,ní ilé ìjọsìn Source of Salvation Ministries,Omisanjana ní Ado-Ekiti ní agbègbè ilé ejọ́ ní Ado-Ekiti láìsí àwíjàre tí ó fi ìdí múlẹ̀.

Ìwé ìròyìn punch.

Adegbenro Islamiyat

Adegbenro Islamiyat is a Yoruba Language Communication expert. She has a wide experience in writing news, stories and articles in Yoruba language. She also doubles as a Programme presenter and voice over expert. Message her on adegbenroislamiyat74@gmail.com

Leave a Reply

Next Post

WHO confirms 4 fresh cases of Ebola in Congo

Wed Apr 22 , 2020
Four new cases of Ebola have been confirmed in the Democratic Republic of Congo (DRC). The World Health Organisation (WHO) Regional Office for Africa confirmed the development on its official twitter account @WHOAFRO on Wednesday. It said, “Four new cases of Ebola have been reported in the past 10 days […]
%d bloggers like this: